Matthew 7:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arakùnrin rẹ kúrò.