Matthew 8:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé òdìkejì òkun, ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, àwọn ọkunrin meji tí wọn ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú itẹ́ òkú, wọ́n wá pàdé rẹ̀. Wọ́n le tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè gba ọ̀nà ibẹ̀ kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀.