Matthew 8:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ lọ!” Wọ́n bá jáde lọ sí inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá dorí kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, wọ́n sáré lọ, wọ́n sì rì sómi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.