Matthew 8:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọn ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí ààrin ìlú, wọ́n lọ ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó ní ẹ̀mí èṣù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti nṣọ wọn si sá, nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ si ilu, nwọn ròhin ohun gbogbo, ati ohun ti a ṣe fun awọn ẹlẹmi èṣu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí-èṣù.