Matthew 8:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ìlú bá jáde lọ pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó kúrò ní agbègbè wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wò o, gbogbo ará ilu na si jade wá ipade Jesu; nigbati nwọn si ri i, nwọn bẹ̀ ẹ, ki o le lọ kuro li àgbegbe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jésù. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbégbé wọn.