Matthew 9:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Kò sí ẹni tíí fi ìrépé aṣọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìrépé aṣọ titun náà yóo súnkì lára ògbólógbòó ẹ̀wù náà, yíya rẹ̀ yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ.