Matthew 9:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, nwọn gbé ọkunrin kan ti o li ẹ̀gba wá sọdọ rẹ̀, o dubulẹ lori akete; nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọkunrin, tújuka, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí ẹní rẹ̀. Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”