Matthew 9:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jésù sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afọnfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń paríwó.