Matthew 9:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde.