Matthew 9:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jésù bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”