Matthew 9:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”