Matthew 9:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìyìn rere ìjọba, ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn.