Micah 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kọja lọ, iwọ ará Safiri, pẹlu itiju rẹ ni ihòhò: ara Saanani kò jade wá; ọ̀fọ̀ Beteseli yio gba iduro rẹ̀ lọwọ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kọjá lọ ni ìhòòhò àti ni ìtìjú, ìwọ tí ó ń gbé ni Sáfírì. Àwọn tí ó ń gbé ni Sáánánì kì yóò sì jáde wá. Bétésélì wà nínú ọ̀fọ̀; A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.