Micah 1:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ olùgbé Lákísi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Síónì, nítorí a rí ìré-òfin-kọjá Ísírẹ́lì nínú rẹ̀.