Micah 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará Juda, ẹ fá irun orí yín láti ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ yín tí ẹ fẹ́ràn; kí orí yín pá bí orí igún, nítorí a óo kó àwọn ọmọ yín ní ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ ara rẹ di apari, si rẹ́ irun rẹ nitori awọn ọmọ rẹ ẹlẹgẹ́; sọ apári rẹ di gbòro bi idì; nitori a dì wọn ni igbèkun lọ kuro lọdọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára, sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún, nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.