Micah 1:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fétísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí OLÚWA alààyè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, OLÚWA láti inú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀ wá.