Micah 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li emi o ṣe Samaria bi òkiti pápa, ati bi gbigbin àjara: emi o si gbá awọn okuta rẹ̀ danù sinu afonifojì, emi o si ṣi awọn ipalẹ rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà. Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì. Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.