Micah 1:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi li emi o ṣe pohunrere, ti emi o si ma hu, emi o ma lọ ni ẹsẹ lasan, ati ni ihòho: emi o pohunrere bi dragoni, emi o si ma kedaro bi awọn ọmọ ògongo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí, èmi yóò sì sunkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún: èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ihòòhò Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.