Micah 2:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ègbé ni fún àwọn tí wọn ń gbìmọ̀ ìkà, tí wọ́n sì ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn. Nígbà tí ilẹ̀ bá sì mọ́, wọn á ṣe ibi tí wọn ń gbèrò. Nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wọn láti ṣe é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EGBE ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ́ mọ́ nwọn nṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún àwọn tí ń gbérò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti se é.