Micah 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Dájúdájú, n óo kó gbogbo yín jọ, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, n óo kó àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ: n óo kó wọn pọ̀ bí aguntan, sinu agbo, àní bí agbo ẹran ninu pápá, ariwo yóo sì pọ̀ ninu agbo náà, nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jákọ́bù; Èmi yóò gbá ìyókù Ísírẹ́lì jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.