Micah 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí; ó ní, “Wò ó, mò ń gbèrò ibi kan sí ìdílé yìí; tí ẹ kò ní lè bọ́rí ninu rẹ̀; ẹ kò ní rìn pẹlu ìgbéraga, nítorí pé àkókò burúkú ni yóo jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi ni Oluwa wi; Kiyesi i, emi ngbimọ̀ ibi si idile yi, ninu eyiti ọrùn nyin kì yio le yọ; bẹni ẹnyin kì yio fi igberaga lọ: nitori akokò ibi ni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA wí pé: “Èmi ń gbérò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.