Micah 2:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni ẹnikan yio pa owe kan si nyin, yio si pohunrere-ẹkun kikorò pe, Ni kikó a kó wa tan? on ti pin iní enia mi: bawo ni o ti ṣe mu u kuro lọdọ mi! o ti pin oko wa fun awọn ti o yapa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà; wọn yóò sì pohùn réré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; OLÚWA ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”