Micah 3:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó-ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nítorí owó. Ṣíbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, wọ́n sì wí pé, “Ní tòótọ́, OLÚWA wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”