Micah 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn wolii tí wọn ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà, tí wọn ń kéde “Alaafia” níbi tí wọ́n bá ti ń rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn tí wọn ń kéde ogun níbi tí kò bá ti sí oúnjẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa wi niti awọn woli ti nṣì awọn enia mi li ọ̀na, ti nfi ehín wọn bù ni ṣán, ti o si nkigbe wipe, Alafia; on ẹniti kò fi nkan si wọn li ẹnu, awọn na si mura ogun si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń sí àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.