Micah 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, alẹ́ yín yóo lẹ́ ṣugbọn àwọn aríran yín kò ní rí nǹkankan, òkùnkùn yóo kùn, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín kò ní rí iṣẹ́ wò. Ògo àwọn wolii yóo wọmi, òkùnkùn yóo sì bò wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina oru yio ru nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; òkunkun yio si kùn fun nyin, ti ẹnyin kì o fi le sọtẹlẹ; õrùn yio si wọ̀ lori awọn woli, ọjọ yio si ṣokùnkun lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè ṣọ tẹ́lẹ̀ Oòrùn yóò sì yọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.