Micah 4:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ma rọbi, si bi, ọmọbinrin Sioni, bi ẹniti nrọbi: nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbẹ́, iwọ o si lọ si Babiloni; nibẹ̀ ni a o gbà ọ; nibẹ̀ ni Oluwa yio rà ọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má a yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Síónì, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsìn yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Bábílónì; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni OLÚWA yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.