Micah 4:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLÚWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa ó sì máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀.” Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde wá, àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti Jérúsálẹ́mù.