Micah 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.