Micah 5:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nisinsinyii, a ti fi odi yi yín ká, ogun sì ti dótì wá; wọ́n fi ọ̀pá na olórí Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NISISIYI gbá ara rẹ jọ li ọwọ́, Iwọ ọmọbinrin ọwọ́: o ti dó tì wa; nwọn o fi ọ̀pa lu onidajọ Israeli li ẹ̀rẹkẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ọmọbìnrin ọ̀wọ́ ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Ísírẹ́lì ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.