Micah 5:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Ísírẹ́lì yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì.