Micah 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Idà ni wọn yóo fi máa ṣe àkóso ilẹ̀ Asiria ati ilẹ̀ Nimrodu; wọn yóo sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Asiria, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ilẹ̀ wa tí wọ́n sì gbógun tì wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Ásíríà run, àti ilẹ̀ Nímíródù pẹ̀lú idà tí a fà. Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ inú ìpínlẹ̀ wa.