Micah 5:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì látí ọ̀dọ̀ OLÚWA wa, bí ọ̀wàrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.