Micah 5:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin àwọn aláìkọlà ní àárin àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrin àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrin agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fàá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.