Micah 6:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti a pa aṣẹ Omri mọ́, ati gbogbo iṣẹ ile Ahabu, ẹ si rìn ni ìmọ wọn; ki emi ba le sọ ọ di ahoro, ati awọn ti ngbe inu rẹ di ẹ̀gan: ẹnyin o si rù ẹgan enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omiri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Áhábù, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”