Micah 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò àti ohun tí Bálámù ọmọ Béórì dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣítímù dé Gígálì, kí ìwọ ba le mọ òdodo OLÚWA.”