Micah 6:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ti fi hàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí í ṣe rere, àti ohun tí OLÚWA ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Ṣùgbọ́n láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.