Micah 7:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì sí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì sí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.