Micah 7:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóo rí i, ojú yóo sì ti ẹni tí ń pẹ̀gàn mi pé, níbo ni OLUWA Ọlọrun mi wà? N óo fi ojú mi rí i; òun náà yóo wá di àtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìta gbangba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọta mi yio ri i, itiju yio si bò ẹniti o wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun rẹ wà? oju mi yio ri i, nisisiyi ni yio di itẹ̀mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.