Micah 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan yóo wá sọ́dọ̀ yín láti ilẹ̀ Asiria títí dé ilẹ̀ Ijipti, láti ilẹ̀ Ijipti títí dé bèbè odò Yufurate, láti òkun dé òkun, ati láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọjọ na ni nwọn o si ti Assiria wá sọdọ rẹ, ati lati ilu olodi, ati lati ile iṣọ́ alagbara titi de odò, ati lati okun de okun, ati oke-nla de oke-nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Ásíríà àti ìlú ńlá Éjíbítì àní láti Éjíbítì dé Yúfúrátè láti òkun dé òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.