Micah 7:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọn óo fi ẹnu gbo ilẹ̀ bí ìgbín, pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì ni wọn yóo jáde bí ejò, láti ibi ààbò wọn; ninu ìbẹ̀rù, wọn óo pada tọ OLUWA Ọlọrun wá, ẹ̀rù rẹ yóo sì máa bà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o lá erùpẹ bi ejò, nwọn o si jade kuro ninu ihò wọn bi ekòlo ilẹ: nwọn o bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa, nwọn o si bẹ̀ru nitori rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.