Micah 7:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọwọ́ wọn méjèèje ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákóso ń bèèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.