Micah 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn. Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùsọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.