Nahum 2:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi dojukọ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, emi o si fi kẹkẹ́ rẹ̀ wọnni joná ninu ẹ̃fin, idà yio si jẹ ọmọ kiniun rẹ wọnni run: emi o si ke ohun ọdẹ rẹ kuro lori ilẹ aiye, ohùn awọn ojiṣẹ rẹ li a kì yio si tún gbọ́ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kíyèsíi èmi dojú kọ ọ́,” ni OLÚWA awọn ọmọ ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn awọn òjíṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tán gbọ́ mọ́.”