Nahum 2:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo, wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede; wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù, wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro. Wọn sì dàbí ètúfú iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.