Nahum 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A tú ayaba sí ìhòòhò, a sì mú un lọ sí ìgbèkùn, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí, wọ́n ń rin bí oriri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀, wọn a sì máa lu àyà wọn.