Nahum 3:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè