Nahum 3:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.