Nahum 3:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kun fún ìrora Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ni orí ta ni, ìwà buburu rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo?