Nahum 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe, tí wọ́n fanimọ́ra, ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró, ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a; nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ, ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrú nipa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.