Nahum 3:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe, n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú; n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ ojú yóo sì tì ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi dojú kọ ọ́,” ni OLÚWA awọn ọmọ ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.